Verse 1:
Ilé-ifè ni orí’run ayé
Ìlú Oòduà baba Yorùbá
Èdùmàrè tó dá wa sí’fè
Kó máse ba ’fe jé mó wa l’órí
K’Olúwa kó maa ràn wá se.
Verse 2: (Refrain)
Ifè Oòyè, E jí gìrì
E jí gìrì, k’e gbé Ifè ga
Olórí aye ni’fè Oòyè
K’á múra láti tè s’íwájú
Òràmfè On’ílé iná
Oòduà a wèriri jagun
Òkànlén’írún irúnmolè
E gbé ’fè lé’kĕ ’sòro gbogbo
Verse 3:
Ilé-ifè b’ojúmó ti mó wá
Ìlú àsà on ìlú èsìn
Gbogbo Yorùbá e káre ’fè
Ká lo w’ohun àdáyébá t’ó jo’jú
Ilé Oòduà Ifè l’ó wà
Opá Òràn’yàn; Ilé-Ifè ni.’
Boji Morèmi Ilé-Ifè ni
Ará, e káre ’fè Oòdáyé.
Repeat Refrain